Ijapa ati Iya- Ẹlẹpa
Ni igba lailai awọn enia ati ẹranko ngbe lẹgbẹ ara wọn, wọn nsọ ede kanna, wọn si nhuwa bakan na. Ni ilu Ijapa, ti a npe ni Magunwa, iyan mu gidi gan-an ni; ko si nkankan ti ẹnu njẹ – ko s’agbado, ko s’iṣu, ko si ere.
Laipẹ, ilu njoro, gbogbo awọn ẹranko t’o ngbe ilu na bẹrẹ si i ku nikọọkan, enia nku, papa awọn ọmọde. Idaamu de ba awọn ẹranko ilu na; nwọn mu owo l’ọwọ nwọn ko r’onjẹ ra;
Ni ọjọ kan Ijapa gbọ ti awọn enian kan nsọrọ pe:
“Ṣe a maa duro k’ebi pa wa ku ni? Lati ilu keji ni awọn kan ti maa nra onjẹ.”
Onjẹ pọ ni ilu keji ti a nwi yi, ti a npe ni Idaha, ọja ibẹ ma nkun akunya ni ọjọ ọja ni.
“Ti awa ko ba yọ’lẹ a le ra’ja ni ọja yi. A dẹ le wa ọja ta pẹlu.”
Ijapa rẹrin nitori pe ajọfẹ ni; ijẹ-ọfẹ ti mọ l’ara. Ba wo lo ṣe maa kuro ni ilu rẹ lati lọ si ilu keji nigbati o le tọrọ onjẹ ni ilu rẹ? Ko le lọ wa nkan ta n’ibẹ. Iṣe nla ni yẹn!
Ṣe Ijapa ma jẹ k’ebi pa nwu ku ni?
Ijapa wa ro ninu ara rẹ pe:
“Bawo ni mo ma ri onjẹ ọfe ni ilu keji yi?”
Nigboya o ronuja ọgbọn kan ti oun yio ta – pe oun a lọ si ọja na lati tọrọ onjẹ dipo pe ki oun ra j’a abi k’oun ta j’a. Ijapa ba gbera ni arọ kututu, ni ọjọ-ọja-kọla, o dorikọ Magunwa, ilu keji.
Ijapa rẹrin nitori pe ajọfẹ ni; ijẹ-ọfẹ ti mọ l’ara.
Ba wo lo ṣe maa kuro ni ilu rẹ lati lọ si ilu keji nigbati o le tọrọ onjẹ ni ilu rẹ?
Ko le lọ wa nkan ta n’ibẹ. Iṣe nla ni yẹn!
Ṣe Ijapa ma jẹ k’ebi pa nwu ku ni?
Ijapa wa ro ninu ara rẹ pe:
“Bawo ni mo ma ri onjẹ ọfe ni ilu keji yi?”
Nigboya o ronuja ọgbọn kan ti oun yio ta – pe oun a lọ si ọja na lati tọrọ onjẹ dipo pe ki oun ra j’a abi k’oun ta j’a.
Ijapa ba gbera ni arọ kututu, ni ọjọ-ọja-kọla, o dorikọ Magunwa, ilu keji.
Nigbat’o de bẹ, o rin yika ọja oriṣiriṣi t’o wa nibẹ, o wa ṣakiyesi pe awọn enia lọpọlọpọ kun bẹ.
Ijapa wipe:
“Maa tun pada l’ọla, ọjọ-ọja, ti ọja miran ma wa.”
Ijapa si pada lọ si ilu rẹ.
Ni ọjọ keji, Ijapa tun gbera o dorikọ ilu keji na. Nigba t’o tun de bẹ, o rin yika ọja t’o wa nibẹ, larin awọn enia to kun ọja, ti nho gee.
Igba yi lo ṣakiyesi Iya-Ẹlẹpa ti isọ rẹ wa ni kọrọ kan n’ibi abawọja.
Inu Ijapa dun.
Ẹpa yiyan jẹ onjẹ ti o fẹran lọpọlọpọ, oju rẹ si wọ ẹpa ti Iya-Ẹlẹpa yi nyan ta.
O ba pinnu pe ti oun k’o ba ri onjẹ jẹ ni ibomiran tabi ẹni t’o le fun oun l’owo, oun lati jẹ ninu ẹpa yi.
Ijapa ba nṣọ Iya-Ẹlẹpa yi bi o ṣe nyan ẹpa rẹ, ni okere, ti o npolowo ẹpa na:
“Ẹlẹ́pà yíyan ré o! Ẹwa bà mi rà n’bẹ!”
Ẹsẹkẹsẹ ni awọn enia ti pe jọ ni wa’ju isọ Iya-Ẹlẹpa ti wọn nra ẹpa yiyan yi. Ijapa sun mọ isọ na o si wipe:
“Ko si ẹpa yiyan t’o daa t’o ti rẹ, Iya-Ẹlẹpa. O nta sansan si mi n’imu l’a t’okere.”
Iya-Ẹlẹpa ko kọ’bi a’ra si nkan ti Ijapa sọ.
O sọ fun Ijapa pe:
“Ṣe orope mi o m’ọ nipa rẹ, Ijapa?
Mo mọ pe o ni le san’wo fun ẹpa mi.
Ajọfẹ ni ọ; ijẹ-ọfẹ ti mọ ọ lara.
Kuro n’iwa ju mi, jare!”
Ijapa b’inu rẹpẹtẹ nitori gbogbo enia t’o wa ni t’osi ni nwọn gbọ nkan ti Iya-Ẹlẹpa nsọ.
Ni Ijapa ba lọ ba Okete, o dẹ s’ọ fun pe:
“Ma ko ọpọlọpọ ekurọ fun ọ t’o ba le tete ba mi gbẹ isa lati idi igi nla kan ni ọja Idaha titi de abẹ isọ IyaẸlẹpa k’ilẹ t’o mọ.”
“Gba pe maa ba ọ ṣe iṣe na daadaa.”
Okete da l’ohun.
Inu rẹ dun, nitoripe Okete f’ẹran ekurọ pupọ.
L’oru ọjọ-ọja-kọla, Ijapa ba bo ‘ra r‘ẹ mọ abẹ ilẹ, ninu isa yi, ni ọgangan isọ Iya-Elẹpa, o wa fi ewe di
oju iho na ni idi igi.
B’o ti d’arọ ọjọ-ọja Iya-Ẹlẹpa tẹ atẹ ẹpa yiyan rẹ, o si da’na o nyan ẹpa tuntun ninu agbada.
Ẹpa tutu wa ni ẹgbẹ rẹ ati agbọn n‘inu omi tutu.
Iya-Elẹpa ba bẹrẹ si npolowo ẹpa na:
“Ẹlẹ́pà yíyan ré o!
Ẹwa bà mi rà n’bẹ!”
Gbogbo ọja ba kun. Ẹpa bẹrẹ si i tasansan.
Ijapa ba bẹrẹ si i kọrin t’o dun bayi pe:
Ẹlẹ́pà yi, Ẹlẹ́pà yi
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ò bá jó lọ bí Ọ̀yọ́ ilé Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ò bá jó lọ bí Ọ̀fà Mọjọ̀
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ǹg bá wò‘dí igbá dé ọ́ o
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú, Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú, Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹlẹ́pà yi, Ẹlẹ́pà yi Pẹrẹpẹrẹpeu.
Mà jó lọ bí Ọ̀yọ́ ilé
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Mà jó lọ bí Ọ̀fà Mọjọ̀
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ǹg bá wò‘dí igbá dé ọ́ o
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú,Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú, Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹrẹpẹrẹpeu.
Bi Ijapa ti nkọrin yi, ti o dẹ nlu’lu pẹlu, ni ohun rẹ maa lọ s’oke a si tun maa lọ s’ilẹ to wa di orin aramada. Bi Iya-Ẹlẹpa ti gbọ orin ti o dun bayi nipa ẹpa yiyan rẹ, l’o ba ju igbakọ t’o fi nyan ẹpa rẹ silẹ kia kia, l’o ba mu ijo jo. Ijapa tun t’ẹnumọ orin rẹ na.
“Ki lo ṣe Iya-Ẹlẹpa ti o njo bayi?” awọn ero ọja t’o gbọ orin na nsọ l’arin ara wọn. Ṣugbọn bi wọn ṣe nwo ti njo, wọn ko mọ ‘gba ti awọn na mu ‘jo jo. Gbogbo ọja ba da patapata. Gbogbo awọn enia ninu ọja yi jo lọ jinnajinna, awọn ti o nt’aja ati awon ti nra’ja, laironukan ohun ti nwọn ba wa si ọja yi mọ.
Ijapa ba ra jade lati isa t’o gba wọ abẹ ilẹ, o w’ọtun o w’osi, o ri pe ọja ti da, o si ko gbogbo ẹpa yiyan Iya-Ẹlẹpa, o wa gba inu igbo sa pada lọ si Magunwa. Nitoripe gbogbo ọja da pau, o pinnu pe ti ohun ba tun wa ni ọjọ-ọja ti mbọ ohun a ji ẹgbogbo nkan miran ti nbẹ ni ọja Idaha.
“Ẹpa yiyan ko to lati jẹ lojojumọ. Maa ko ninu nkan wọnyi s’inu isa mi, maa dẹ ko’yoku lọ s’ile. Mi o ṣa le maa wa lojojumọ s’ọja? Okete ṣe daada fun mi o!.”
Nigbati Iya-Ẹlẹpa ati awọn ero ọja Idaha ti jo jo titi kọja ọja ti o ku diẹ ki wọn b’ara wọn ni ilu keji, ni orin aramada Ijapa ka l’oju wọn.
Nwọn w’o ara wọn l’oju pẹlu itiju.
“Ki l’a nṣe nibi? Tabi nkankan nṣe wa ni?”
Nigbati wọn de ọja ni nwọn ṣi wa mọ ofo ti o ti ṣe Iya-Ẹlẹpa. Ijapa ti ko gbogbo ẹpa yiyan rẹ.
“Ki l’o maa wa ṣe bayi, Iya-Ẹlẹpa? Tabi wa mu ọrẹ kan dani ni ọjọ-ọja ti mbọ, ki o ma ṣọ igba rẹ, ki eleyi ma ba tun ṣẹ’lẹ mọ?” awọn ero ọja bere l’ọwọ Iya-Ẹlẹpa. Iya-Ẹlẹpa ṣi dupẹ l’ọwọ wọn.
Iya-Ẹlẹpa ba mu ọrẹ rẹ gidi kan wa ṣ’ọja ni ọjọ-ọja.
“Emi a joko maa wo ‘di igba fun ọ, k’ole ma ba a ji ẹpa rẹ”
orẹ rẹ wi.
Iya-Ẹlẹpa tun tẹ atẹ ẹpa yiyan rẹ, o si da’na o nyan ẹpa tuntun ninu agbada. Ẹpa tutu wa ni ẹgbẹ rẹ ati agbọn n‘inu omi tutu. Iya-Ẹlẹpa ba bẹrẹ si yan ẹpa rẹ, o npolowo ẹpa na:
“Ẹlẹ́pà yíyan ré o! Ẹwa bà mi rà n’bẹ!”
Gbogbo ọja ba tun kun ti nho gee. Ẹpa bẹrẹ si i tasansan.
Ijapa ba tun bẹrẹ si i kọrin oloyinmọmọ bayi pe:
Ẹlẹ́pà yi, Ẹlẹ́pà yi Pẹrẹpẹrẹpeu. Ò bá jó lọ bí Ọ̀yọ́ ilé Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ò bá jó lọ bí Ọ̀fà Mọjọ̀
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ǹg bá wò‘dí igbá dé ọ́ o
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú, Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú, Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹlẹ́pà yi, Ẹlẹ́pà yi Pẹrẹpẹrẹpeu. Mà jó lọ bí Ọ̀yọ́ ilé
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Mà jó lọ bí Ọ̀fà Mọjọ̀
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ǹg bá wò‘dí igbá dé ọ́ o
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú,Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú, Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹrẹpẹrẹpeu.
Bii tatehinwa, bi Ijapa ti nkọrin yi ni ohun rẹ ma lọ s’oke a si tun ma lọ s’ilẹ to wa di orin aramada.
Bi Iya-Ẹlẹpa ti gbọ orin ti o dun bayi nipa pa yiyan rẹ, l’o ba ju igbakọ t’o fi nyan ẹpa rẹ silẹ kia kia, lo ba
tun mu’jo jo.
Ijapa tun t’ẹnumọ orin rẹ na, o si nlu’lu. Ọrẹ Iya-Ẹlepa ba mu’jo jo.
Awọn ero ọja t’o gbọ orin na t’o si ri Iya-Ẹlepa ati ọrẹ rẹ ti njo, nwọn ko mọ gba ti awọn na mu’jo jo. Gbogbo ọja ba tun da patapata.
Gbogbo awọn enia ninu ọja yi jo lọ jinnajinna, awọn ti o nt’aja ati awọn ti nra’ja, laironukan ohun ti nwọn ba wa si ọja yi mọ.
Ijapa ba tun ra jade lati isa t’o gba wọ abẹ ilẹ, o w’ọtun o w’osi o ri pe ọja ti da, o si ko onjẹ tẹrun, gbogbo ẹpa yiyan Iya-Ẹlẹpa l’o ko ko ko, o wa gba inu igbo sa pada lọ si Magunwa.
Nigbati Iya-Ẹlẹpa ati awọn ero ọja Idaha tun ti jo jo titi kọja ọja ti o ku diẹ ki nwọn b’ara wọn ni ilu keji, ni orin aramada Ijapa ka loju wọn.
Nwọn tun w’o ara wọn l’oju pẹlu itiju, nwọn si tun bi ara wọn pe:
“Ki l’a nṣe nibi? Tabi nkankan nṣe wa ni?”
Nigbati nwọn de ọja ni nwọn ṣi wa mọ ofo ti o ti ṣe Iya-Ẹlẹpa ati gbogbo wọn.
“Eleyi ma nk’ọja ala! Nkankan nṣẹ’lẹ ni ọja yi; ko dẹ gbọdọ ṣẹ’lẹ mọ.”
Nwọn wa ṣe ipade, nwọn si ran ikọ lati lọ sọ fun Ọba ilu Idaha ohun t’o ti ṣẹ’lẹ na. O ya Ọba lẹ’nu.
“Bawo ni wọn ṣe le sọ wipe wọn ko mọ nkan ti wọn nṣe? Bawo ni gbogbo ọja ṣe ma da pau nitoripe gbogbo awọn enia ibẹ l’o ti jo lọ jinnajinna. Ṣe wọn ko gbọ orin oloyinmọmọ ri ni? Ṣebi obinrin ni ọpọlọpọ awọn ero ọja? Awọn obinrin fẹran ijo pupọ. O maa nko si wọn l’ori, nwọn dẹ ma nfẹ ki enia maa wo wọn bi nwọn ṣe njo s’ibi jo s’ohun…“
“Kabiyesi, awọn ọkunrin na wa l’arin wọn.”
“Boya inu awọn ọkunrin ti nwọn ti nwa bi nwọn ṣe le sunmọ elomiran ninu awọn obinrin yi dun, nitoripe nwọn le jo jo jo pẹlu wọn!”
Gbogbo enia ba ku s’ẹrin, nwọn ko mọ nkan ti nwọn ma sọ mọ.
“Ko si a nlọ k’abọ, t’o ba di ọjọ ọja ti mbọ gbogbo awọn ọdẹ ilu o lọ ba wa sọ ọja na, ki ole ti nkọrin nipa Iya-Ẹlẹpa, “Ẹlẹpa yi, ẹlẹpa yi” ma baa tun ko Iya-Ẹlẹpa ati awọn yoku ni nkan mọ. Pipa ni wọn ma pa ẹn’ti nkọrin”, Ọba paṣẹ.
Ni ọjọ ọja ni gbogbo awọn ọdẹ ba gbe ibọn wọn, nwọn lọ duro kakiri inu ọja na. Awọn l’o kọkọ d’ebẹ papa. Bi gbogbo ọja tun ti kun ti nho gee, ti Iya-Ẹlẹpa ti tẹ atẹ ẹpa yiyan rẹ, ti o da ẹpa sinu agbada l’ori ina, ti o bẹrẹ si i yan ẹpa, ti ẹpa bẹrẹ si i tasansan, t’obinrin na tun polowo rẹ:
“Ẹlẹ́pà yíyan ré o! Ẹwa bà mi rà n’bẹ!”
bẹ ni Ijapa, t’o ti sa sinu isa yẹn loru, lo tun bẹrẹ si i kọrin bayi pe:
Ẹlẹ́pà yi, Ẹlẹ́pà yi Pẹrẹpẹrẹpeu. Ò bá jó lọ bí Ọ̀yọ́ ilé Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ò bá jó lọ bí Ọ̀fà Mọjọ̀
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ǹg bá wò‘dí igbá dé ọ́ o Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú, Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú, Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹlẹ́pà yi, Ẹlẹ́pà yi Pẹrẹpẹrẹpeu. Mà jó lọ bí Ọ̀yọ́ ilé Pẹrẹpẹrẹpeu.
Mà jó lọ bí Ọ̀fà Mọjọ̀
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ǹg bá wò‘dí igbá dé ọ́ o Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú,Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú, Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹrẹpẹrẹpe.
Ẹ̀pà pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹrẹpẹrẹpeu.
Bi Iya-Ẹlẹpa ati gbogbo wọn, ẹn’ti nra, at’ẹn’ti nta, ti gbọ orin na, ti Iya-Ẹlẹpa ti ju igbakọ t’o fi nyan ẹpa s’ilẹ, t’o mu ‘jo jo, ni gbogbo wọn bẹrẹ si i jo.
Awọn odẹ ti nwọn gbe ibọn le ejika wọn, jo tititi laironukan ohun ti nwọn ba wa si ọja mọ.
Nwọn ti gbagbe pe pipa l’awọn fẹ pa ẹn’ti nkọrin aramada yi.
Gbogbo ero ọja ati awọn ọdẹ jo lọ jinnajinna; gbogbo ọja tun da pau.
Ijapa ba tun ra jade lati ibi t’o gba wọ abẹ ilẹ, o ko onjẹ tẹrun, o salọ si ilu rẹ.
Orisirisi ọja ti awọn enian nta l’o ko lọ patapata.
Nigbati Iya-Ẹlẹpa ati awọn ero ọja Idaha ti jo jo titi kọja ọja ti o ku diẹ ki wọn b’ara wọn ni ilu keji, tun ni orin aramada Ijapa ka loju wọn.
Nwọn fura pe ole ti tun ja l’ọja. Nwọn dẹ ṣakiyesi pe awọn ọdẹ ilu ti nwọn wa s’ ọja lati pa ẹn’ti nkọrin wa ni arin wọn.
“Ki ni gbogbo wa nṣe nibi?
Ẹyin ọdẹ ilu ti ẹ wa ṣọ ọja lati pa ẹn’ti nkọrin, ki ole yi ma baa ko wa ni nkan mọ! Ibọn yin da? Oyẹ k’oju ti yin!”
Awọn ọdẹ wa lọ sọ fun Ọba pe ole ti tun ja l’ọja. Ọba ni pe:
“Bawo ni ẹnyin odẹ ilu ṣe ma sọ fun mi pe orin ti ole na nkọ dun tobẹ gẹẹ t’o jẹ pe ẹ ko mọ ‘gba ti ẹnyin papa bẹrẹ si i jo lọ jinnajinna laironukan ohun ti ẹ ba lọ si ọja mọ – titi ole na fi ko ọja t’ẹ nṣo? Ẹnyin wọnyi, ẹ o tilẹ mọ isẹ nyin niṣe!
“Boya o ti pẹ ti ẹnyin odẹ ti jo. Ṣe nitori pe ẹ ri awọn obinrin pupọ ti nwọn jo larin nyin ni ẹ fi gbagbe pe pipa lẹ fẹ pa ole ti nkọrin “Ẹlẹpa yi, ẹlẹpa yi”. Awọn obinrin wa gbadun ijo ju! Nwọn ma njo gan-an, nwọn ma njo ajokara!”
Lẹhin eyi, Ọba paṣẹ ikede pe ẹnikẹni t’o ba le ba ‘oun mu ole ti nkọrin na ki o jọwọ wa si aafin wa ri oun. Gbogbo enia l’oriṣiriṣi yọj’u: babalawo, oniṣegun, nwọn wa ba Ọba, nwọn ni awọn yio sa ipa awọn lati mu ole na.
“O dara, mo faramọ ọn, ẹ lọ gbiyanju. N’Igbati ọjo-ọja miran ba tun de, gbogbo nyin a lọ si ọja ẹ si pin ara nyin kakiri”
Ṣugbọn bi tatẹhinwa, Ijapa tun bẹrẹ si i kọ orin armada rẹ. Gbogbo enia l’o tun mu ijo jo, nwọn lọ jinna rere kuro ni ọja. Ijapa tun rapala jade, o ko onjẹ lọ tẹrun, o wa gba inu igbo sa pada lọ si ilu rẹ tayọtayọ.
Ọba ba ranṣẹ pe gbogbo awọn irunmọle ilu. Awọn Osanyin wa nibẹ. Nigbati nwọn de iwaju Ọba, Ọba bẹ wọn pe:
“L’ọjọ-ọja ijọ mẹta oni, ẹ o ba mi mu ole ti nkọrin na.”
“L’ọjọ-ọja na Ọsanyin ẹlẹsẹmẹwa, ẹlẹsẹmẹsan, ẹlẹsẹmẹjo, titi de ẹlẹsẹmẹta wa nibẹ.
Ko si Ọsanyin ẹlẹsẹmeji rara. Ọsanyin Ẹlẹsẹkan ni ko wa n’ijọ na. Ṣugbọn ni ọjọ -ọja nigbati nwọn l’ọ si ọja Idaha, ti Ijapa si bẹrẹ si i kọrin rẹ bi o ti maa nkọ, mimu l’awọn na mu ijo jo.
Gbogbo wọn jo jo, nwọn kan l’ẹsẹ. Gbogbo awọn ero ọja jo lọ tititi, Ijapa si tun ri aye ko onjẹ tẹrun, o wa gba inu igbo sa pada si ilu rẹ.
Ni owurọ ọjọ keji Ọsanyin Ẹlẹsẹkan ji l’ọ si aafin Ọba. O sọ fun Ọba pe:
“Kabiyesi! Ẹ f’ọkanbalẹ, emi yio mu ole abami na.”
“Ọsanyin Ẹlẹsẹkan, ẹsẹ kansoso lo ni; awọn Ọsanyin bi irẹ ti ẹsẹ wọn to marun, mẹfa titi de mẹwa, ni nwọn ti gbiyanju. Ṣe o wa fi mi ṣe yẹyẹ ni?”
“Kabiyesi! Ẹ ṣa f’ọkanbalẹ. Maa mu ole na.”
“Ko bu’ru. L’ọ si ọja ni ọjọ-ọja ti mbọ, k’o si ṣ’eto atimu ole na.”
Lẹhin eyi, Ọba bẹrẹ si i ro’nu ọna wo ni nwọn tun le ṣ’eto atimu ole naa.
“Isọ Iya-Ẹlẹpa wa n’ibi abawọja ni kọrọ kan.
Maa ran awon oṣisẹ mi meji lọ s’ọja pẹlu, ki nwọn lọ rin kakiri inu ọja ni itosi isọ Iya-Ẹlẹpa.”
Nigbati awọn oṣisẹ yi pada de nwọn sọ fun Ọba pe isa kan nbẹ lati idi igi nla kan ni ọja titi de abẹ isọ Iya-Ẹlẹpa, ni ọgangan isọ na.
Ewe pupọ lo b’oju iho t’o wa ni idi igi, ati ni ‘bomiran.
Oriṣiriṣi ounjẹ si lo kun inu isa yi.
Ọba fun nwọn l’aṣẹ pe ki awọn oṣisẹ yi na lọ s’ọja ni ọjọ-ọja ti mbọ, pẹlu kondo.
Nigbati o di ọjọ-ọja, Ọsanyin Ẹlẹsẹkan mu oolu rẹ dani, o si gbe ewiri rẹ, o lọ si ọja, o lọ lugọ si eti isọ Iya-Ẹlẹpa. O da ina agbẹdẹ, o si fi oolu rẹ bọ ina, o fin’na mọ ọ titi o fi pọn rẹkẹsẹ.
Awon oṣisẹ Ọba na mu kondo wọn dani, nwọn lọ duro ni ọgangan isọ Iya-Ẹlẹpa, ni’bi ti ewe digaga oju iho isa ni idi igi nla na.
Gbogbo wọn f’ara pamọ daadaa.
“Bẹrẹ si yan ẹpa, Iya-Ẹlẹpa! Polowo ẹpa rẹ!” nwọn sọ fun Iya-Ẹlẹpa.
Iya-Ẹlẹpa ba tun polowo rẹ bayi pe:
“Ẹlẹ́pà yíyan ré o! Ẹwa bà mi rà n’bẹ!”
Ẹpa bẹrẹ si i tasansan. Ijapa ba k’ẹnu bọ orin bi tatẹhinwa pe:
Ẹlẹ́pà yi, Ẹlẹ́pà yi Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ò bá jó lọ bí Ọ̀yọ́ ilé Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ò bá jó lọ bí Ọ̀fà Mọjọ̀
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ǹg bá wò‘dí igbá dé ọ́ o Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú, Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú, Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹlẹ́pà yi, Ẹlẹ́pà yi Pẹrẹpẹrẹpeu. Mà jó lọ bí Ọ̀yọ́ ilé Pẹrẹpẹrẹpeu.
Mà jó lọ bí Ọ̀fà Mọjọ̀
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ǹg bá wò‘dí igbá dé ọ́ o Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú,Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú, Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹrẹpẹrẹpe.
Ẹ̀pà pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹrẹpẹrẹpeu.
Ni Iya-Ẹlẹpa ati gbogbo ero ọja yoku ba jo lọ jinnajinna, ṣugbọn Ọsanyin Ẹlẹsẹkan ko le jo pẹlu ẹsẹ kan; ko y’ẹsẹ nibi t’o lugọ si.
Nigbati Ijapa tun rọra ra jade, t’o ro pe ko si ẹnikankan l’ọja mọ, b’o ti bẹrẹ si i ko ẹpa ni Ọsanyin Ẹlẹsẹkan ba ki oolu rẹ t’o ti pọn rẹkẹsẹ, o ki bọ imu Ijapa.
Awọn oṣisẹ Ọba na ti jade, t’awọn ti kọndo, nwọn bẹrẹ si i ba Ijapa ni kọndo.
Ijapa ba k’igbe pẹlu iro’ra, o si nbẹ’ bẹ, o ni:
“Ẹ jọwọ ẹ ma pa mi o!”
Bayi ni Ọsanyin Ẹlẹsẹkan ba mu Ijapa, o si wi fun un pe:
“Ijapa, mo mu ọ loni! Aṣe iwọ l’o ti maa nko wọn ni nkan ni ọja lati ijọ yi. O ya k’a lọ, odi ile Ọba!”
Ọsanyin Elẹsẹkan mu u Ijapa de iwaju Ọba. Awọn oṣisẹ Ọba na tele wọn.
Nigbati nwọn ma fi de aafin Oba, Ijapa ti fẹ ku pẹlu iro’ra. Niṣe l’o nke, ti gbogbo ara nro. Ko t’ilẹ le rin daadaa mọ. Nigbati Ọba ri i pe Ijapa ni ole ti nkọrin, ẹnu ya a, o ni:
“Ijapa, aṣe iwọ l’o ti maa nko wọn ni nkan ni ọja lati ijọ yi. Ki ni a o tiṣe ọ bayi?”
Ijapa ko le s’ọrọ daadaa mọ:
“Kabiyesi! Ẹ jọwọ ṣ’anu fun mi. Mi ko ni ṣ’oru nkan ti mo ṣe mọ.
Maamaa kọrin, maa si ma lu duru mi fun idaraya.
Mi ko ni fi orin le awọn ero ọja ati ẹlomiran lọ, ti nwọn maa fi jo lọ jinnajinna laironukan ohun ti nwọn ba wa si ọja mọ.”
“Se iwọ ro wipe iwọ nikan ni o mọ kọrin oloyinmọmọ ati pe orin na l’o jẹ ki awọn enia jo lọ tititi? Ni aafin mi, awọn enia ti wọn nkọrin oloyinmọmọ wa. T’irẹ ko ya’tọ. O ti pẹ ti awọn ero ọja ati ẹlomiran ti jo ni.”
“Kabiyesi! Bi mo ti ṣe nkọrin oloyinmọmọ pẹlu ilu mi y’atọ si ti ẹlomiran. Gbogbo enia ti o ba gbọ orin na ma mu’jo jo, nwọn ma jo lo jinnajinna, tititi ti nwọn fi ma gbagbe ibi ti nwọn wa.”
Ọba ku s’ẹrin:
“Ko s’orin ti o le dun tobẹ gẹẹ t’o jẹ pe awọn enia ko ni mọ ‘gba ti awọn bẹrẹ si i jo tititi – jinnajinna laironukan ohun ti nwọn ṣe! Maa fun ẹnikẹni t’o ba le kọ oru orin na ni ọpọlọpọ owo ati oriṣiriṣi nkan.”
Eleyi ya gbogbo awọn ijoye ni aafin Ọba l’ẹnu. Inu wọn ko dun rara. Ọba paṣẹ pe ki nwọn lọ ti Ijapa m’ọle titi oun o fi d’ajọ fun nkan t’o ṣe si Iya-Ẹlẹpa, awọn ero oja, awọn ọdẹ, ati gbogbo ẹlomiran ti nwọn lọ si ọja, ti nwọn pin ara wọn kakiri lati mu ole ti nkọrin. Lẹhin eyi, Ọba gbagbe nipa Ijapa patapata, o nba iṣẹ lọ ni aafin.
Ni ọjọ kan ti ẹsẹ gbogbo awọn ijoye pe ni aafin Ọba, nwọn gbọ orin:
Ẹlẹ́pà yi, Ẹlẹ́pà yi Pẹrẹpẹrẹpeu. Ò bá jó lọ bí Ọ̀yọ́ ilé Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ò bá jó lọ bí Ọ̀fà Mọjọ̀
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ǹg bá wò‘dí igbá dé ọ́ o Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú, Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú, Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹlẹ́pà yi, Ẹlẹ́pà yi Pẹrẹpẹrẹpeu. Mà jó lọ bí Ọ̀yọ́ ilé Pẹrẹpẹrẹpeu.
Mà jó lọ bí Ọ̀fà Mọjọ̀
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ǹg bá wò‘dí igbá dé ọ́ o Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú,Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹ̀ú, Ẹ̀pà pẹ̀ú
Pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹrẹpẹrẹpe.
Ẹ̀pà pẹrẹpẹrẹpeu.
Ẹ̀pà pẹrẹpẹrẹpeu.
Ggbogbo awọn ijoye bẹrẹ si i jo.
Ọba papa k’o mo ‘gba ti oun na dide, ti o mu ‘jo ‘jo.
Pẹlu ade lori rẹ, o gun ẹsin rẹ.
Ẹni t’o gbe agboorun Ọba ko mọ’gba ti oun sọ ọ sibikan k’oun le gbadun ijo na.
Ọba fi ẹsin rẹ jo titi ade fi takiti sọnu.
Awon ijoye rẹ si tẹle e, awọn na wa lori ẹsin tiwọn.
K’a ma fa a gun lọ titi, gbogbo wọn mu ijo jo, nwọn jo gan-an, nwọn jo ajokara, nwọn lọ jinna rere.
Nigbati eedi da loju gbogbo wọn ni nwọn to fura pe Ijapa lo ti nkọrin aramada rẹ.
Gbogbo awọn ara ilu t’o ri wọn nki Ọba ni, “Kabiyesi!”.
Oju ti Ọba ati awọn ijoye rẹ.
Nigbati nwọn pada si aafin, Ọba ni ki nwọn lọ mu Ijapa wa si’waju oun.
Ọba mu ileri rẹ ṣẹ, ṣugbọn o sọ fun Ijapa pe:
“O ko gbọdọ de Idaha mọ lailai.
Ọba Magunwa dẹ ma le ọ kuro ni ilu yẹn, nitori iwa buruku ti o hu si gbogbo enia ni Idaha.”
Inu Ijapa dun, o dupẹ l’ọwọ Ọba Idaha. Nigbati o pada si Magunwa o ba lọ ra igba pẹlu owo ti Ọba Idaha fun, lati fi bo ẹyin rẹ, ki o maa baa j’oro l’ọwọ ẹnikẹni bi Ọsanyin Ẹlẹsẹkan ati awọn oṣisẹ Ọba. O gbe igba na si ẹyin rẹ, igba na dẹ lẹ mọ ẹyin rẹ patapata.
Idi rẹ niyi ti Ijapa fi ni igaba l’ẹyin rẹ.